Awuse Tuntun Se Ifilole Kiko Afin Oba Tuntun Ni Ipinle Eko

Loni ti se ojo kejidinlogun  osu karun odun 2021 ni onile,alejo ati awon otokulu ilu ko ara won jo pelu oriade oba Awuse  ti ilu onigbongo  Maryland ni ipinle eko se ifilole kiko afin oba tuntun ni ipinle Eko

Kabiesi oba alade Oba Oluwasegun Ajasa Adeyemi Olaside Awuse 1 ti ilu onigbongbo Maryland leko wipe lojojumo naa ni  idagba soke nwaye ti gbogbo nkan si n yato atipe lati igba iwase ni ko ti si afin oba ti ale pe ni Afin Oba onigbongbo,tori obakoba to ba je inu ile ara awon ni won  ma n joba si,leyi ti oba oluwasegun ati Awon ijoye re ro wipe kise ohun to bo jumu.

Kabiesi Oba Olusegun Awuse 1 ti ilu onigbongo Maryland ni ipinle eko wipe ilu onigbongo je ilu kan pataki ni ipinle eko ti eto oro aje won ko se fi oworo seyin,ti ilu naa si fi aye gba onile ati alejo Hausa Yibo Yoruba ati awon eya miran ti won si jo ngbe igbe aye alafia laisi jagidijagan. 

Kabiesi tun so pe ajose po ti odanmoran ni o wa larin awon ati ile ise ijoba  ibile Onigbongbo pelu be si ni Awon to nsoju  won ni ile igbimo Asofin agba mejeji nilu Abuja naa ko gbeyin ninu sise iranlowo akaimoye fun ilu onigbongo ati awon olugbe ibe.

Kabiesi wipe laipe yi ni Senator Adeola yayi wa ri ero imuna wa (transformer) fun awon ni ilu onigbongo, bee si Asofin Faleke naa se iranlowo mimu isetan kuro lawujo fun opolopo omo ilu onigbongo.

Kabiesi so ninu oro re pe Ogun koda bi iyan o,atipe bi aba ni ki apinya loni kii se ikan tororun,toripe ninu ilu onigbongbo  yi fun bi apeere awon ti ri Hausa tabi yibo to je pe won ti lo adota odun ti o si jepe nibi ni won bi gbogbo omo won si,ti elomiran ninu won ko mo ona ile mo,ilu eko ni won npe ni ilu won.

 Oba Olusegun Awuse 1 ti ilu onigbongbo Maryland ni ijoba ibile onigbongo LCDA wipe ojuse olori ni lati  ma wa ona abayo fun gbogbo omo leyin re,bi otileje pe opolopo iwa rere yi ni awon jogunba lati ara obi to bi awon,olorun tun fi emi isore si awon lokan idi re re to fi je pe bi enikan ba sunkun wole awon ogbodo rerin jade,kabiesi wa ro gbogbo awon alase ati otokulu ilu lati je orisun iranlowo fun awon eniyan, be lo si ro awon odo pe ki won rora se lori eto idibo si ipo ijoba ibile nilu eko.

Olori Odo ti ilu onigbongo Maryland naa kin oro kabiesi lehin pe bi aba nso nipa ilu ti alafia ti joba ni ipinle eko oni ilu onigbongo ni, o so ninu oro pe awon agbofin ro ko wa mu enikan pe o jale tabi o hu iwa odanran kan ri ninu ilu awon,bi awon ba fe se ayeye tabi ohun kan ni awon ma nrase pe awon olopa,o wa ro gbogbo awon odo ki won tesiwaju ninu iwa rere won,papajulo bi awon se fe wonu eto idibi fun ijoba ibile, o wipe lati bi odun mokandinlogun ti won ti da ile ise to risi idagbasoke ilu iyen onigbongbo LCDA wipe omo ilu onigbongo ko ti se ri,o ni sugbon olorun lo ma yan eniyan sipo pe olorun yio se eyi ti odara fun awon ninu eto ibibo naa.

Olori odo wipe o to oludije mefa ti o fe gbe igba idibo alaga ijoba ibile naa,o wa ro awon odo pe enikeni ti ibo ba mu ki awon jo fowo so wo po.

Alhaji Ali Muhammed tii se Seriki Hausa ni ijoba ibile naa wipe o ti le ni 
ogoji odun ti oun ti wa ni ilu onigbongo Maryland, pe ko ti si akosile jagidijagan kankan ninu ilu naa,beesi ni ajose po ti o danmoran wa larin Hausa Yibo ati Yoruba, ti eto aroaje ilu naa si nlo bi otiye,o wa dupe pupo lowo kabiesi Awuse fun idari won ati gbogbo oloye patapata fun ifilole Afin oba tuntun ti won fe ko ni ilu onigbongo.

No comments

Powered by Blogger.