Itesiwaju Ninu Sinsin Olorun Pelu Iberu Leyin Awe Ramadan-Oloye Badmus lo so be

Loni ti se ayajo ojo ajodun Awe Ramadan ni oloye Oluwatoyin Badmus Baale alahusa  fonrere yi si gbogbo elesin islam jakejado agbaye pe ki won ri pe awon tesiwaju ninu sisin olorun pelu iberu,pe ki o kan maje ninu awe ti asese pari yi nikan 

Oloye Badmus tise baale alahusa lo so eyi pelu awon akoroyin wa ninu afin re ni Alahusa ni ijoba ibile ikeju ti se olu ilu ipinle eko.

Baale so Pataki idi ti afi gbodo tesiwaju ninu iberu olorun ati yiyago fun ese
Oloye Badmus,baale alahusa so wipe bi aba kiyesi ninu akoko awe Ramadan yi, pe opolopo eniyan lo ma nwa ninu irele ti won si ma nkiyera ninu ohun gbogbo ti won nse ti o mu  ki alafia ati itura wa paapa julo ninu orile ede .

Baale alahusa ni ijoba ibile Ikeja tii se Olu ilu ipinle eko wipe ni odo tawon nbi, awon ni asa ati ise, pe bi elesin islam tabi elesin igbagbo ba nse ajodun tabi ohunkohun nise ni gbogbo awon  yio gbaruku tira awon, ti ko ni si iyato laarin elesin mejeji,o wa ro gbogbo omo orileede Nigeria lati tesiwaju ninu ibagbe po 

Oloye Toyin wipe Ogun ko dabi eko o,atipe kosi ilu ti Ogun tija ti idamu kisi tabi wahala,baale fi orileede Libya ati Pakistan pelu awon ilu ti won ti njagun lowo se apeere  oun ti oju awon omo orileede naa ndojuko lowolowo,pe aka aimoye omo loti di omo olomo,oko ti di oko oloko ti iyawo gan kosi ri ile gbe mo.

Ni ti iselu baale soo wipe kosi ijoba to pe tan, ko da lati ilu America ti awon ti wale wa je oye, baale wipe won ko pe tan o,adura ni a nilo lati ma fi ran ijoba lowo,o wa so nipa akitiyan ati ise ribiribi ti ijoba ipinle Eko nse lowolowo latiri pe awon olugbe ipinle eko gbe igbe aye irorun.

Bakanna ni Imam agba mosalasi jimon ti ilu alahusa na tun so nipa iberu,wipe aini iberu awon alase tabi olorun ki je ki orileede ki o wa ni alafia,

Baba wipe iberu olorun ni ipilese ogbon,o wa ro gbogbo eniyan lati tesiwaju ninu iberu olorun ati awon alase tabi olori leyin awe Ramadan.

Okan lara awon olori odo ninu esin Islam ni mosalasi jimon ti alahusa ni ijoba ibile Ikeja tise olu ilu ipinle Eko,Alhaji Wasiu dupe Latakia lowo Baale ati gbogbo awon ti won dasi awe Ramadan ti odun yi pe ki olorun tun bo ma se alekun ore fun won.

Alhaji Wasiu lo soro idupe yi latari ifowosowopo ti won gba ninu awe Ramadan yi  pe bi o tilejepe ni odun ti o koja arun Pandemic ti o gbode kan ko gba enikeni laye lati sajoyo odun naa papo,sugbon odun yi ko ri be,

O wa dupe gidi lowo gbogbo awon ti won se iranwo fun aseyori awe ti odun yi lopolopo ti o si ro gbogbo awon omo orile ede yi paapa julo awon odo pe ki won gbe ilu Ogun tabi ipinya ti si egbe kan,pe gbogbo eto aye owo olorun lowa.

No comments

Powered by Blogger.