Kafilat Bolomope Di Iyalode Tuntun Ti Ilu Ede Ni Ipinle Osun.

Loni ti se ojo keedogbon osu keje odun 2021 ni Kabiesi Oba Minirudeen Adesola lawal Laminisa 1 timi ti ilu ede nipinle osun  fi oloye kafilat Bolomope Osunsoko je oye Iyalode tuntun ti  ilu ede.

Kabiesi wipe bi nkan o ba se ese,ese ki sadede se o,pe iware ti oloye kafilat Bolomope ti hu seyin lo se okunfa oye naa,kabiesi wipe eniti oye nakan ti dagba leyi ti gbogbo wa si mo pe enikeni ti yio je oye iyalode gbodo je enikan ti o lakikanju,togbajumo ti osi je olowo tabi ipo lawujo, sungbon olorun lo ma nfi eniyan sipo,ohun ti olorun ba si ti ko kosi eni ti o le yipada.kabiesi wipe olorun loyan kafilatu Bolomope sipo naa.

Oba laminisa tun so ninu pro re pe gbogbo bi nkan ti se nsele eto olorun,kabiesi wipe iya oba ki se olowo tabi oloro sugbon a won ise rere ti iya tobi won rise sole ni won nje,oba lawal laminisa iya oba ti ni anfani lopolopo igba lati fun oba ni mojele je ti enikeni ko si ni no,sugbon iya oba ko se be rara o ti won fi file sasobora,enikeni toba se iru eyi enikan ko gbodo gbagbe iru eniyan be,kabiesi wa ro gbogbo omo bibi ilu ede pe ki won fowosowopo pelu Iyalode tuntun ki ilu kole toro tuba tuse.

Opolopo Oriade nipinle osun naa ni won fi arahan nibi ayeye iwuye naa,ti awon oba alade so gbangba gbangba pe opolopo ogbon ni awon tun ko latara kabiesi oba timi ti ilu ede fun ilana ati isese ti won tele laifi ti figba kan bo okan ninu.
Ninu awon gbajugbaja ti o wa sibi ayeye iwuye naa ni Alh Ganiyu Bakare  Baale Alekuwodo ni ipinle osun ti won si tun je alaga egbe oniburedi ni ipinle Osun iyen bread bakers association of Nigeria ti eka . ipinle osun,oloye Bakare wipe oye Iyalode ki se oye lasan,atipe enikeni to yio je olori obinrin gbodo je enipataki ti o si je adari rere.

Iyalode  ti oba Timi fi je oye yi,pe awon naa ni oye ohun to si,Baale alekuwodo dupe lowo Oba Minirudeen Lawal Timi Ede fun titele ilana ati Asa ile wa..

Baale alekuwodo tesiwaju ninu ajose po ti o moyanlori pelu ijoba ipinle osun pelu egbe awon oniburedi ni ipinle osun.be ni baale tun ro ijoba ipinle osun lati tesiwaju pelu egbe won ninu ajosepo todanmoran,ti won sidupe pupo lowo gbogbo omo egbe oniburedi ni ipinle osun fun ifowosowopo won.

Okan lara awon otokulu ti osi tunje oloye pataki ni ipinle osun paapa julo lati ile-ife Oloye Olusola Oke Akinrogun Oranmiyan ile ife ti o si tunje alase ati oludasile Asiko laye bread so nipa oye iyalode larin ilu,oloye Akinrogun wipe oye iyalode je oye Pataki ti alee pe ni oba binrin,olori gbogbo obinrin,bi iyalode tuntun se je yi oti di iya okunrin iya obinrin,omode ati agbagba ilu ede.
O wa fi da gbogbo omo bibi ilu ede loju pe laipe yi iyato otun yio bere si farahan pelu idagba soke otun  nilu ede latipase iyalode tuntun yi.

No comments

Powered by Blogger.