Ooni Ni Baba OPC - Osibote lo so be

Odun Olojo je Odun kan pataki ninu Iran Yoruba,o je Odun ti olodumare da ojo ti o si so ojo ni oruko,o si tun je Odun ti kaabiesi Oonirisa ma nse Adura fun gbogbo Iran Yoruba jakejado gbogbo agbaye.

Ile-ife je Orirun Iran Yoruba nibi ti oju timo wa,beesi ni Oonirisa tise arole Oduduwa je baba awa (OPC)Oodua people Congress ti o sise Pataki fun wa lati se ayeye Odun Olojo pelu won.

Prince Osibote tiise Aare egbe Oodua People Congress (OPC)lo so oro yi pelu awon akoroyin wa nibi ayeye Odun Olojo ni ile-ife,Aare wipe ninu gbogbo Oba alade nile Yoruba ti won je alatilehin egbe OPC pe ko si okankan ti alefi atilehin ti Oba Adeyeye Oguwusi Ojaja se akawe re,pe baba je ogunna gbongbo ti ndato lenu igbin ninu atilehin egbe awon.

O wa so wipe odidandan fun awon lati wa se ayeye odun Olojo yi pelu won.

Ni afikun oro Aare egbe OPC,Prince Osibote so wipe bi ipile ba baje ko si ohun ti olododo yio se,atipe eniti ti ebi npa ti ko si ona abayo osese ki iru enibe ki o jale,atipe bi ojuse awon olori base je a ma se okunfa ihuwa si omo eyin,o ni omo egbe OPC ti ko sise ti e si ni ki o wa ma sise eto abo ti ko ni gbedeke iye owo osu ti ongba,oni iru enibe yio si iwa hu.Aare wipe nikete ti awon gba isakoso egbe OPC gege bi Aare egbe naa,igbese akoko nipe awon da gbogbo omo egbe OPC pada si enu ise won nitori owo to ba dile ni rore so,ti awon sise agbekale oniruru eto idanileko fun gbogbo omo egbe OPC.

Lori Oro Amotekun,Prince Osibote wipe awon ni ajose po bi o tile jepe agbekale re ko ti muna doko,sugbon ajosepo wa larin won,Aare wipe bi osu meji sehin ni oun lo re ri Gomina Akeredolu nigba ti o ranse si oun ti awon si jo so opolopo oro lori eto abo ilu paapa julo ile yoruba

Okan lara awon eka kan ninu egbe OPC ti amosi gallant OPC ni oludasile eka ohun se akawe iru eniti prince Osibote ti se Aare egbe OPC je,ninu iforowanilenuwo ni ogbeni naa ti apeja re nje Minister ti so pe Aare Osibote je Asiwaju rere ti o si mo eto  o to,se emope eni ti o ba mo ona ni too.

Minisita wipe lati igba ti Aare Osibote ti di olori egbe awon ni iyato to yanranti ti ba egbe OPC ti ko si si anfani kankan fun omo egbe lati siwahu tabi se asemose kankan.

O tun wa so ninu oro re pe bi ko ba sepe awon ba wa si iru ode ayeye bayi ti awon si wo aso egbe,oni enikeni ko le mo pe omo egbe OPC ni awon nitori inu bayi ni ida koso ngbe.o wa fi asiko dupe gidi lowo Aare won fun ise takun takun ati awon atunse gbogbo ti won to se,be lo si tun ki Oonirisa arole Oodua Oba Adewusi Enitan Ojaja Ii fun ti odun Olojo pe won yio se amodun o.

Bakanna ni Igbakeji Aare egbe yeye moolu nile ife, iyen alhaja Ramat Ologundudu naa so pataki odun olojo.aya ologundudu wipe odun olojo je odun ti olodunmare da ojo ti o so ojo ni oruko.
Odun olojo ki se fun ile-ife nikan o wa fun gbogbo omo Yoruba jakejado gbogbo agbaye sugbon Kabiesi Ooni ni kan naa ni won ma nse ajodun odun naa lati wure fun gbogbo omo Yoruba to wa ni gbogbo agbaye.
Alhaja Ramotu wa wipe egbe awon naa je egbe kabiesi Oonirisa,pe baba wa Arole Oodua Oba Adeyeye Ogunwusi Ojaja ni won ni egbe yi
Aya ologundudu tun so ninu afikun oro re pe,omo ti eniyan o ba ko ni yio gbe ile ti ako ta,o di dandan fun awon obi lati ko omo won ni awon asa wa,ki asa  ma ba parun.
Ni akotan Alhaja Ramotu wa lo anfani yi lati dupe pupo lowo Oloye Eyinade Adelekan ti se ekeje iyalode ti ile-ife fun akitiyan won lati mu egbe yeye moolu duro,o wipe iya Eyinade ni asiri ewa awon ti aya ologundudu si se adura pe ki olorun olodunmare tubo fun mama ni emi gigun.

No comments

Powered by Blogger.