Iku Aalafin:Gbogbo Oyo nsofo

Bi o ti wu ki oriade tabi orun ti nlo ejigba ileke je elesin to,boya elesin musulumi tabi onigbagbo,ohun ti a pe ni isese tabi asa gbodo farahan.

Looto ni awon elesin musulumi se ojuse ti won gege bi esin ti kaabiesi iku baba yeye Oba Lamidi Adeyemi lll alafin Oyo nse 

Sugbon nigba ti odi deede ago mefa irole ni awon onisese de tiwon si le gbogbo awon eniyan jade lafin lati se oro ikehin fun alafin.

Ko ti si okankan lara alafin to je ninu ilu  ti won sin won ni osan gangan bi ko ba se loru ganjo,bakanna ni ti isinku Oba lamidi Adeyemi naa je o.ni bara ni won si oku alafin Oyo si.

Ninu ibanikedun lori iku alafin Oyo,Babaloja General nipinle Oyo, Alh S.K Jimoh ti won je olori gbogbo iyaloja babaloja nipinle Oyo wipe iku alafin Oyo bawon lojiji nitoripe ko si eni to ro iku si Baba lakoko yi,sugbon ohun gbogbo ye olorun.
Oloye jimoh wipe awon le fe Oba Lamidi Adeyemi sugbon olorun feran won ju awon lo.
O wa ki gbogbo ebi ati awon iyawo ati awon omo pe won Ku iroju o,pe ki olorun duro ti won o
No comments

Powered by Blogger.