Ojuse Esin Musulumi Ninu Sise Ijoba Rere - Sheilk Bello


Gebe bi a ti mope asiko awe gbigba je asiko kan pataki fun Awon elesin musulumi jakejado orile ede agbaye, o je asiko ifokansi, nini idapo pipe pelu Olorun ati asiko isoore fun omo nikeji tabi fun awon alaini .

Ninu Ojuse yi ni ijo ANSA-UD-DEEN Society of Nigeria eka ti Yoruba ni wuse2 ninu Abuja se agbekale idanileko lori ojuse esin musulumi ninu sise ijoba rere ninu orile ede ti onidanileko si je Sheilk Muideen Bello baba oniwaasi agbaye ati agba woli ninu esin musulumi.

Alhaji Bello yanna na pataki ati ojuse esin musumumi ninu ijoba orile pe, Enikeni ti yio je olori gbodo je eniti oni okan olorun, iberu olorun ati sise ife olorun ni gbogbo igba.

Oniwasi Agbaye naa wipe iberu olorun ni ipilese ogbon ati ise rere gbogbo, ti o si wipe ipile isejoba rere gbodo ni iberu olorun ninu, lati ipase iberu olorun ni iru Olori tabi Aare orileede yio ti ni ife ati se dada ni ipo re ni gbogbo igbakugba tabi ninu isejoba 
Lai ni iberu olorun iru olori bee kole  ni ife awon eniyan lokan de bipe yio se rere.
Sheilk Bello wa dupe pupo lowo awon to se agbekale Idanilelo naa pe ose pataki ni akoko ti ijoba tuntun fe bere ni orile ede Nigeria.
Sheilk naa wa ro awon Oludasile eto idanileko yi pe ki wa gbogbo ona lati je pe fonran eto naa te Aare tuntun ti won se dibo yan lowo iyen Asiwaju Bola Ahmed Tinubu , ireti awon eniyan ninu Asiwaju ga gan , pe ki Aare tuntun fi iberu olorun se ipile ise-ijoba re ki o le ba ni Aseyori .

Ninu Awon eniyan pataki ti o wa nibi idanileko naa ni Adajo Agba fun Orileede Nigeria chief Justice Olukayode Ariwoola CJN, Senator Elect Hon.Aliyu Ahmed Wadada, Hon Mallam Muktar Shagaya ati  Mama re Bola Shagaya, Oloye Chief mrs Mujidat Folasade Ojo Omo Tinubu pelu opolopo Awon lekanlekan ti won fi Owo won gbe Esin Musulumi ga ninu Orileede Nigeria paapa julo ninu omo Yoruba to ngbe ilu Abuja.
Oloye Folasade Ojo Omo Tinubu naa so ninu oro pe, ipa Obinrin ninu esin ni lati se iranwo ati atilehin  fun Oko re, ki iru obinrin naa si je eniti oni iberu Olorun laifi tebe se. No comments

Powered by Blogger.