IROYIN FELIFELI:Gbagbagba Ni Ooni Duro Ti Omo Oodua Loke Oya

Ninu eto isokan ati ifowosowopo omo Yoruba kaakakiri orile agbaye ti kabiesi Ooni riisa nse lati ripe Iran Yoruba wa papo laisi gbonmisi omioto.Ninu re ni egbe omo Oodua community ti won nse atipo ni awon ipinle ilaorun mokankandinlogun (19 northern state) iyen ni oke-oya ti ko ara won jo ninu ipade asekagba opin odun nilu Abuja tiise olu-ilu orileede Nigeria.

Ipade yi dalori bi isokan yio tiwa larin omo Yoruba ti won yio si ma ni ife ara won pelu ife si enikeni ti won ba yan ni olori tabi oba ilu naa.

Ni bi ipade yi ni Ooni riisa ti so oju abe niko pe odi dandan fun awon Gomina ilu kokan ti omo Yoruba wa lati ni ifowosowopo pelu won paapaa julo awon oba Yoruba ni awon ipinle naa.Oba Dokita Adebisi Segun Layade alara odaye ti ile-ife ti o wa soju fun Oba Adeyeye ojaja ll Ooni of ife losi aso loju eegun oro ohun.

Oba alara odaye wipe gbogbo ipa ni kabiesi Ooni risa ngba lati ripe awon Gomina ipinle kookan ti awon omo Yoruba wa ni won ni ajosepo ti odanmoran ti awon Gomina yio si le ma fun awon oba ilu kokan ni iwe eri pe Oba ni won nse ni awon ipinle naa.kabiesi wa ro gbogbo omo Yoruba ti o wa ni oke oya pe kiwon ni ifowosowopo pelu awon olori won pelu awon Oba ilu naa.

Bakanna ni okan lara awon asoju Yoruba ti oje iyalode nipinle ilaro oorun lati ilu jigawa iyen Hajia Adisahid Adekanola ti osi tun je asoju awon obinrin nipinle north soo wipe gbogbo akitiyan awon ni lati ripe won ko fi owo ro omo Yoruba sehin ni oke-oya,,ti o si dupe lowo olorun fun Aare ti olorun yan fun won Dokita Suara tii se Aare Omo Oodua community  ni oke-oya,wipe Aare o sun be ni won wo lati ripe omo Yoruba naa ni eto labe ijoba awon ipinle loke oya.
Iyalode Adekanola so wipe ipade yio je asekagba ti odun yi to osi  waye lati mu itesiwaju ati idagbasoke ba egbe omo Oodua community ni oke oya.

Lakotan Aare egbe omo Oodua community loke oya naa wa dupe Pataki lowo Kabiesi Oba Adeyeye ogunwusi ojaja ll,fun atilehin won ti o si gbadura ki olorun tubo lora emi won,ti Aare si fi da kabiesi loju  pe awon ati gbogbo alakoso egbe omo Oodua community ko ni siwo ise titi ti gbogbo Omo Yoruba yio fi de ile ileri.

No comments

Powered by Blogger.