Gomina Seyi Makinde Lo So Mi Di Igbakeji Alaga Ibadan North East -Mary Esomior lo so be

Bi aba si wa laye ki a ma so ireti nu nigba kankan nitori olorun ko gbagbe enikeni bi asiko ba ti to olorun yio gbe iranlowo dide.

Igbakeji alaga tuntun ni ijoba ibile Ibadan north lo so eyi ninu iforowanilenu wo pelu akoroyin wa oduduwa watch nile ise ijoba ibile naa nilu Ibadan ti se olu ilu ipinle oyo

Arabirin Marry Esomior ti se igbakeji alaga ijoba  ibile naa lo so di mimo pelu awon oniroyin  loni nigba ti ongba awon alejo ti won wa ki ku orire ninu ile ise ijoba ibile naa.

Mary Esamior wipe bi ko ba si ti olorun to ran Gomina Seyi Makinde si oun lati di eniyan pataki oni  tani oun,

Hon.Mary ti se igbakeji alaga ibile ibadan north wipe ninu ile ni oun wa ti ipe de lati odo gomina  pe niwon ba igba ti won ti dibo yan eni ti yio dije fun ipo alaga ibile ninu egbe PDP, pe oun ni awon mu lati je igbakeji alaga, arabinrin Mary wipe bi ala ni oro naa ri ni oju oun to ripe oun ko ni ero re rara bi o ti wu ki o mo.
lotito baba oun je oloselu ti o gbajugbaja ni ipinle Oyo sungbon oun ko tile riro nigbakan ri pe oun le di igbakeji alaga ni ipinle oyo,o ni fun idi eyi oun dupe pupo lowo olorun ati idupe Pataki lowo ololajulo Onimoero Gomina Seyi Makinde fun anfani ti Gomina fun oun lati wa ninu ijoba re ni ijoba ibile,

O wa so wipe ni gbogbo ona ni oun yio gba lati je igbakeji alaga rere ati lati se iranlowo fun alaga oun lati se aseyori ninu ijoba naa.
O tun lo anfani lati dupe pupo lowo awon oludibo ti won dibo fun egbe PDP ni ojo Satide pe won se pupo ti o si se ileri pe ki won ki o ma mura sile lati je ere ise ti won ti se lati dibo yan alaga ati oun si ipo alaga ati igbakeji ni ijoba ibile naa,pe gbogbo ere ti eniyan ma nje ninu iselu ni gbogbo eniyan ni ijoba ibile awon yio je.

No comments

Powered by Blogger.